Psalms 24

Ti Dafidi. Saamu.

1 aTi Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
2Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun
ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

3Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?
Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
4 bẸni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
tí kò sì búra èké.

5Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,
àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
6Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

7Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
Kí ọba ògo le è wọlé.
8Ta ni ọba ògo náà?
Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,
Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
9Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10Ta ni Ọba ògo náà?
Olúwa àwọn ọmọ-ogun
Òun ni Ọba ògo náà. Sela.
Copyright information for YorBMYO